Lúùkù 15 BMY

Òwe Àgùntàn Tó Sọnu

1 Gbogbo àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sì súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

2 Àti àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé ń kùn pé, “Ọkùnrin yìí ń gba ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.”

3 Ó sì pa òwe yìí fún wọn, pé,

4 “Ọkùnrin wo ni nínú yín, tí ó ní ọgọ̀rún-ún àgùntàn, bí ó bá sọ ọ̀kan nù nínú wọn, tí kì yóò sì tọ ipaṣẹ̀ èyí tí ó nù lọ, títí yóò fi rí i?

5 Nígbà tí ó bá sì rí i tán, yóò gbé e lé èjìká rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀.

6 Nígbà tí ó bá sì dé ilé yóò pe àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóò sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ bá mí yọ̀; nítorí tí mo ti rí àgùntàn mi tí ó nù.’

7 Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ yóò wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà, ju lórí olóòótọ́ mọ́kàndínlọ́gọ́rún-ún lọ, tí kò nílò ìrònúpìwàdà.

Òwe Owó Tó Sọnù

8 “Tàbí obìnrin wo ni ó ní fàdákà mẹ́wàá bí ó bá sọ ọ̀kan nù, tí kì yóò tan fìtílà, kí ó fi gbá ilé, kí ó sì wá a gidigidi títí yóò fi rí i?

9 Nígbà tí ó sì rí i, ó pe àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, ó wí pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀; nítorí mo rí fàdákà tí mo ti sọnù.’

10 Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ń bẹ níwájú àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run lórí ẹlẹ́sẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà.”

Òwe Ọmọ Tó Sọnù

11 Ó sì wí pé ọkùnrin kan ní ọmọ méjì:

12 “Èyí àbúrò nínú wọn wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Baba, fún mi ní ìní tí ó kàn mí.’ Ó sì pín ohun ìní rẹ̀ fún wọn.

13 “Kò sì tó ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, èyí àbúrò kó ohun gbogbo tí ó ní jọ, ó sì mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ òkèrè, níbẹ̀ ni ó sì gbé fi ìwà wọ̀bìà ná ohun ìní rẹ̀ ní ìnákúnàá.

14 Nígbà tí ó sì ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ tan, ìyàn ńlá wá mú ní ilẹ̀ náà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí di aláìní.

15 Ó sì lọ, ó da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ọlọ́tọ̀ kan ní ilẹ̀ náà; òun sì rán an lọ sí oko rẹ̀ láti tọ́jú ẹlẹ́dẹ̀.

16 Ayọ̀ ni ìbá fi jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ ní àjẹyó: ẹnikẹ́ni kò sì fifún un.

17 “Ṣùgbọ́n nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní, ‘Àwọn alágbàṣe baba mí mélòómélòó ni ó ní oúnjẹ àjẹyó, àti àjẹtì, èmi sì ń kú fún ebi níhìnín.

18 Èmi ó dìde, èmi ó sì tọ bàbá mi lọ, èmi ó sì wí fún un pé: Bàbá, èmí ti dẹ́sẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ;

19 Èmi kò sì yẹ, ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́; fi mí ṣe ọ̀kan nínú àwọn alágbàṣe rẹ.’

20 Ó sì dìde, ó sì tọ baba rẹ̀ lọ.“Ṣùgbọ́n nígbà tí ó sì wà ní òkèrè, baba rẹ̀ rí i, àánú ṣe é, ó sì súré, ó rọ̀ mọ́ ọn ní ọrùn, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

21 “Ọmọ náà sì wí fún un pé, Baba, èmi ti dẹ́sẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ, èmi kò yẹ ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́!

22 “Ṣùgbọ́n Baba náà wí fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, Ẹ mú ààyò aṣọ wá kánkán, kí ẹ sì fi wọ̀ ọ́; ẹ sì fi òrùka bọ̀ ọ́ lọ́wọ́, àti bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ̀:

23 Ẹ sì mú ẹgbọ̀rọ̀ màlúù àbọ́pa wá, kí ẹ sì pa á; kí a máa ṣe àríyá:

24 Nítorí ọmọ mi yìí ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù, a sì rí i. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í se àríyá.

25 “Ṣùgbọ́n ọmọ rẹ̀ èyí ẹ̀gbọ́n ti wà ní oko: bí ó sì ti ń bọ̀, tí ó súnmọ́ etí ilé, ó gbọ́ orin òun ijó.

26 Ó sì pe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọn, ó béèrè, kíni a mọ nǹkan wọ̀nyí sí?

27 Ó sì wí fún un pé, ‘Àbúrò rẹ dé, baba rẹ sì pa ẹgbọ̀rọ̀ màlúù àbọ́pa, nítorí tí ó rí i padà ní àlààáfíà àti ní ìlera.’

28 “Ó sì bínú, ó sì kọ̀ láti wọlé; bàbá rẹ̀ sì jáde, ó sì wá í sìpẹ̀ fún un.

29 Ó sì dáhùn ó wí fún bàbá rẹ̀ pé, ‘Wòó, láti ọdún mélòó wọ̀nyí ni èmi ti ń sìn ọ́, èmi kò sì rú òfin rẹ rí: ìwọ kò sì tí ì fi ọmọ ewúrẹ́ kan fún mi, láti fi bá àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe àríyá:

30 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ rẹ yìí dé, ẹni tí ó fi panṣágà ru ọ̀rọ̀ ara rẹ̀, ìwọ sì ti pa ẹgbọ̀rọ̀ màlúù àbọ́pa fún un.’

31 “Ó sì wí fún un pé, ‘Ọmọ, nígbà gbogbo ni ìwọ ń bẹ lọ́dọ̀ mi, ohun gbogbo tí mo sì ní, tìrẹ ni.

32 Ó yẹ kí a ṣe àríyá kí a sì yọ̀: nítorí àbúrò rẹ yìí ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù, a sì rí i.’ ”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24