Lúùkù 5 BMY

Ìpè Awọn Omọ Ẹ̀yìn Àkọ́kọ́

1 Ó sì ṣe, nígbà tí ìjọ ènìyàn ṣún mọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dúró létí adágún Gẹ́nẹ́sárétì,

2 Ó rí ọkọ̀ méjì tọ́ wá létí adágún: èyí tí àwọn apẹja ti sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú wọn, nítorí tí wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn.

3 Ó sì wọ ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ náà, tí í ṣe ti Símónì, ó sì bẹ̀ ẹ́ kí ó tìí sí ẹ̀yìn díẹ̀ kúrò ní ilẹ̀. Ó sì jókòó, ó sì ń kọ́ ìjọ ènìyàn láti inú ọkọ̀ náà.

4 Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ í sọ, ó wí fún Símónì pé, “Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀.”

5 Símónì sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan: ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀.”

6 Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja: àwọ̀n wọn sì ya.

7 Wọ́n sì pe àwọn ẹgbẹ́ wọn, tí ó wà ní ọkọ̀ kéjì, kí wọn kí ó wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n sì wá, wọ́n kó ẹja ọkọ̀ méjèèjì sì kún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì.

8 Nígbà tí Símónì Pétérù sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bá eékún Jésù, ó wí pé, “Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; nítorí ẹlẹ́sẹ̀ ni mí.”

9 Ẹnu sì yàá wọ́n, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, fún àkópọ̀ ẹja tí wọ́n kó:

10 Bẹ́ẹ̀ ni Jákọ́bù àti Jòhánù àwọn ọmọ Sébédè, tí ń ṣe alábàákẹ́gbẹ́ Símónì.Jésù sì wí fún Símónì pé, “Má bẹ̀rù; láti ìsinsin yìí lọ ìwọ ó máa sàwárí àwọn ẹlẹ́sẹ̀.”

11 Nígbà tí wọ́n sì ti mú ọkọ̀ wọn dé ilẹ̀, wọ́n fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lọ.

Ọkùnrin Pẹ̀lú Ẹ̀tẹ̀

12 Ó sì ṣe, nígbà tí Jésù wọ ọ̀kan nínú àwọn ìlú náà, kíyèsí i, ọkùnrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò: nígbà tí ó rí Jésù, ó wólẹ̀, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mí di mímọ́.”

13 Jésù sì na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́!” Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ.

14 Ó sì kìlọ̀ fún u pé, “Kí ó má ṣe sọ fún ẹnìkan: ṣùgbọ́n kí ó lọ, kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí ó sì ta ọrẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Mósè ti pàṣẹ fún ẹ̀rí sí wọn.”

15 Ṣùgbọ́n òkìkí rẹ̀ ń kàn kálẹ̀: tóbẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì jùmọ̀ pàdé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba dídá ara lọ́dọ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àìlera wọn.

16 Ṣùgbọ́n ésù a máa yẹra kúrò, òun á sì máa dáwà láti gbàdúrà.

Jésù wo arọ sàn

17 Ní ijọ́ kan, bí ó sì ti ń kọ́ni, àwọn Farisí àti àwọn amòfin jókòó pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí ó ti àwọn ìletò Gálílì gbogbo, àti Jùdíà, àti Jerúsálémù wá: agbára Olúwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú wọn láradá.

18 Sáà sì kíyèsí i, àwọn Ọkùnrin kan gbé ẹnikantí ó ní àrùn egba wà lórí àketè: wọ́n ń wá ọ̀nà àti gbé e wọlé, àti láti tẹ́ ẹ ṣíwájú Jésù.

19 Nígbà tí wọn kò sì rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi gbé e wọlé nítorí ìjọ ènìyàn, wọ́n gbé e gun òkè àjà ilé lọ, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sí àárín èrò ti òun ti àketè rẹ̀ níwájú Jésù.

20 Nígbà tí ó sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí pé, “Ọkùnrin yìí, a darí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” (Luk 7.48,49.)

21 Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí í gbérò wí pé, “Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀ òdì? Ta ni ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo.” (Isa 43.25.)

22 Jésù sì mọ ìrò inú wọn, ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín?

23 Èwo ni ó yá jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tàbí láti wí pé, ‘Dìde kí ìwọ sì má a rìn’?

24 Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ọmọ ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini…” Ó wí fún ẹlẹ́gbà náà pé, “Mo wí fún ọ, dìde, sì gbé àketè rẹ, kí o sì máa lọ sí ilé!”

25 Ó sì dìde lọ́gán níwájú wọn, ó gbé ohun tí ó dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó yin Ọlọ́run lógo.

26 Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹ̀rù sì bà wọ́n, wọ́n ń wí pé, “Àwá rí ohun abàmì lónì-ín.”

Ìpè Léfì

27 Lẹ́hìn èyí, Jésù jáde lọ, ó sì rí agbowó òde kan tí à ń pè ní Léfì ó jòkòó sí ibi tí ó ti ń gba owó òde, Jésù sì wí fún un pé “Tẹ̀lé mi,”

28 Léfì sì fi ohun gbogbo sílẹ̀ ó sì ń tẹ̀lé e.

29 Léfì sì ṣe àṣè ńlá kan fún Jésù ní ilé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti àwọn mìíràn sì ń jẹun pẹ̀lú wọn.

30 Ṣùgbọ́n àwọn Farisí, àwọn olùkọ́ òfin tí ó jẹ́ ara wọn fi wọ́n hàn sí àwọn ọmọ ẹ̀hìn “èéṣe tí ẹ̀yin fi ń jẹun tí ẹ sì ń mú pẹ́lú àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

31 Jésù dáhùn ó wí fún wọn pé “Ẹni tí ara rẹ̀ le kò nílò oníṣègùm, bí kò ṣe ẹni tí ara rẹ̀ kò dá.”

32 Èmí kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.

A Bèèrè Nípa Àwẹ̀ Lọ́wọ́ Jésù

33 Wọ́n wí fún un wí pé “àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù a máa gbàwẹ̀, wọn a sì máa gbàdúrà, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú sì ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí ṣùgbọ̀n àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ a máa jẹ, wọn a sì máa mu pẹ̀lú.”

34 Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ó seé se kí àwọn àlejò ọkọ ìyàwó máa gbàwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó wà pẹ́lú wọn bí?

35 Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyìí ni wọn yóò gbàwẹ̀.”

36 Ó sì pa òwe yìí fún wọn wí pé: “Kò sí ẹni tó lè ya asọ tuntun kí ó sì rán mọ́, èyí tó ti gbó. Tí ó ba ṣe èyí, yóò ba asọ tuntun jẹ́, èyí tí ó tuntun náà kì yóò ṣe dógba pẹ̀lú èyí tí ó ti gbó.

37 Àti wí pé, kò sí ẹni tí ó lè dá otí wáìnì sínú ògbólógbò awọ, tí ó bá ṣe èyí, wáìnì tuntun yóò fa awọ náà ya, wáìnì náà yóò dànù awo náà a sí.

38 Nítorí náà, ó tọ́ kí á da wáìnì tuntun sínú awọ tuntun.

39 Kò sì ẹni tí yóò fẹ́ láti mu wáìnì tuntun lẹ́yìn tí ó bá ti mu ogbólógbò tán, nítorí yóò wí pé ‘èyí tí ó jẹ́ ògbólógbò dára jù.’ ”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24