1 Jésù sì wọ Jẹ́ríkò lọ, ó sì ń kọjá láàrin rẹ̀.
2 Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan wà tí a ń pè ní Sákéù, ó sì jẹ́ olórí agbowó òde kan, ó sì jẹ́ ọlọ́rọ̀.
3 Ó sì ń fẹ́ láti rí ẹni tí Jésù jẹ́: kò sì lè rí i, nítrorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti nítorí tí òun jẹ́ ènìyàn kúkúrú.
4 Ó sì súré ṣíwájú, ó gun orí igi síkámórè kan, kí ó bà lè rí i: nítorí tí yóò kọjá lọ níhà ibẹ̀.
5 Nígbà tí Jésù sì dé ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i, ó sì wí fún un pé, “Sákéù! Yára, kí o sì sọ̀kalẹ̀; nítorí pé èmi yóò wọ ilé rẹ lóní.”
6 Ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbà á.
7 Nígbà tí wọ́n sì rí i, gbogbo wọn ń kùn, wí pé, “Ó lọ wọ̀ lọ́dọ̀ ọkùnrin tí í ṣe ‘ẹlẹ́sẹ̀.’ ”
8 Sákéù sì dìde, ó sì wí fún Olúwa pé, “Wòó, Olúwa, ààbọ̀ ohun ìní mi ni mo fifún talákà; bí mo bá sì fi èké gba ohun kan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, èmi san án padà ní ìlọ́po mẹ́rin!”
9 Jésù sì wí fún un pé, “Lóní ni ìgbàlà wọ ilé yìí, níwọ̀n bí òun pẹ̀lú ti jẹ́ ọmọ Ábúráhámù.
10 Nítorí Ọmọ Ènìyàn dé láti wá àwọn tí ó nù kiri, àti láti gbà wọ́n là.”
11 Nígbà tí wọ́n sì ń gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó sì tẹ̀ṣíwájú láti pa òwe kan, nítorí tí ó súnmọ Jerúsálémù, àti nítorí tí wọn ń rò pé, ìjọba Ọlọ́run yóò farahàn nísinsin yìí.
12 Ó sì wí pé, “Ọkùnrin ọlọ́lá kan lọ sí ìlú òkèrè láti gba ìjọba kí ó sì padà.
13 Ó sì pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mínà mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ má a ṣòwò títí èmi ó fi dé!’
14 “Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, ‘Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jọba lórí wa.’
15 “Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́-òwò wọn.
16 “Èyí èkínní sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mínà rẹ jèrè owó mínà mẹ́wá sí i.’
17 “Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere! Nítorí tí ìwọ ṣe olóòótọ́ ní ohun kínkínní, gba àṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’
18 “Èyí èkéjì sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mínà rẹ jèrè owó mínà márùnún.’
19 “Olúwa rẹ sì wí fún un pẹ̀lú pé, ‘Ìwọ joyè ìlú márùnún!’
20 “Òmíràn sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, wòó owó mínà rẹ tí ń bẹ lọ́wọ́ mi ni mo dì sínú aṣọ-pélébé kan;
21 Nítorí mo bẹ̀rù rẹ, àti nítorí tí ìwọ ṣe òǹrorò ènìyàn: ìwọ a máa mú èyí tí ìwọ kò fi lélẹ̀, ìwọ a sì máa ká èyí tí ìwọ kò gbìn!’
22 “Olúwa rẹ sì wí fún un pé, ‘Ní ẹnu ara rẹ náà ni èmi ó ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni mí, pé, èmi a máa mú èyí tí èmi kò fi lélẹ̀ èmi a sì máa ká èyí tí èmi kò gbìn;
23 Èé ha sì ti ṣe tí ìwọ kò fi owó mi pamọ́ sí ilé ìfowó pamọ́, pé nígbà tí mo bá dé, Èmi ìbá ti béèrè rẹ̀ pẹ̀lú èlé?’
24 “Ó sì wí fún àwọn tí ó dúró létí ibẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó mínà náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fi í fún ẹni tí ó ní owó mínà mẹ́wàá.’
25 “Wọ́n sì wí fún un pé, ‘Olúwa, ó ní owó mínà mẹ́wàá.’
26 “Mo wí fún yín pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní, ni a ó fifún, àti lọ́dọ̀ ẹni tí kò ní èyí tí ó ní pàápàá a ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.
27 Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá mi wọ̀nyí, tí kò fẹ́ kí èmi jọba lórí wọn ẹ mú wọn wá ìhínyìí, kí ẹ sì pa wọ́n níwájú mi!’ ”
28 Nígbà tí ó sì ti wí ǹkan wọ̀nyí tan, ó lọ ṣíwájú, ó ń gòkè lọ sí Jerúsálémù.
29 Ó sì ṣe, nígbà tí ó súnmọ́ Bẹtifágè àti Bétanì ní òkè tí a ń pè ní Ólífì, ó rán àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
30 Wí pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó kọjú sí yín; nígbà tí ẹ̀yin bá wọ̀ ọ́ lọ, ẹ̀yin ó rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí: ẹ tú u, kí ẹ sì fà á wá.
31 Bí ẹnikẹ́ni bá sì bi yín pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tú u?’ Kí ẹ̀yin wí báyìí pé, ‘Olúwa ń fẹ́ lò ó.’ ”
32 Àwọn tí a rán sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn.
33 Bí wọ́n sì ti ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn Olúwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?”
34 Wọ́n sì wí pé, “Olúwa ń fẹ́ lò ó.”
35 Wọ́n sì fà á tọ Jésù wá: wọ́n sì tẹ́ ẹ wọ́n sì gbé Jésù kà á.
36 Bí ó sì ti ń lọ wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà.
37 Bí ó sì ti súnmọ́ etí ibẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olófì, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀, wọ́n sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run, nítorí iṣẹ́ ńlá gbogbo tí wọ́n ti rí;
38 Wí pé, “Olùbùkún ni Ọba tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!”“Àlààáfíà ní ọ̀run, àti ògo ni òkè ọ̀run!”
39 Àwọn kan nínú àwọn Farisí nínú àwùjọ náà sì wí fún un pé, “Olùkọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.”
40 Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí fún wọn pé, “Mo wí fún yín, Bí àwọn wọ̀nyí bá pa ẹnu wọn mọ́, àwọn òkúta yóò kígbe sókè.”
41 Nígbà tí ó sì súnmọ́ etílé, ó ṣíjú wo ìlú náà, ó sọkún sí i lórí,
42 Ó ń wí pé, “Ìbáṣepé ìwọ mọ̀, lóní yìí, àní ìwọ, ohun tí í ṣe tí àlààáfíà rẹ! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n pamọ́ kúrò lójú rẹ.
43 Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ fún ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò mọ odi bèbè yí ọ ká, àní tí wọn yóò sì yí ọ ká, wọn ó sì ká ọ mọ́ níhà gbogbo.
44 Wọn ó sì wó ọ palẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ; wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ara wọn; nítorí ìwọ kò mọ ọjọ́ ìbẹ̀wò rẹ.”
45 Ó sì wọ inú tẹ́ḿpìlì lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde;
46 Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò olè.”
47 Ó sì ń kọ́ni lójoojúmọ́ ní tẹ́ḿpìlì, Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, àti àwọn olórí àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà láti pa á run.
48 Wọn kò sì rí nǹkan kan tí wọn ìbá ṣe; nítorí gbogbo ènìyàn ṣù mọ́ ọn láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.