25 Ó sì wí pé “Báyìí ni Olúwa ṣe fún mi ní ọjọ́ tí ó ṣíjú wò mí, láti mú ẹ̀gàn mi kúrò láàrin àwọn ènìyàn.”
26 Ní oṣù kẹfà Ọlọ́run sì rán áńgẹ́lì Gébúríẹ́lì sí ìlú kan ní Gálílì, tí à ń pè ní Násárẹ́tì,
27 sí wúndíá kan tí a ṣè lérí láti fẹ́ fún ọkùnrin kan, tí a ń pè ní Jóṣéfù, ti ìdílé Dáfídì; orúkọ wúndíá náà a sì máa jẹ́ Màríà.
28 Ańgẹ́lì náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Àlààáfíà, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ńbẹ pẹ̀lú rẹ”
29 Ṣùgbọ́n ọkàn Màríà kò lélẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà, ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, irú kíkí kínni èyí.
30 Ṣùgbọ́n àńgẹ́lì náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Màríà: nítorí ìwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
31 Ìwọ óò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní JÉSÙ.