28 Ańgẹ́lì náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Àlààáfíà, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ńbẹ pẹ̀lú rẹ”
29 Ṣùgbọ́n ọkàn Màríà kò lélẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà, ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, irú kíkí kínni èyí.
30 Ṣùgbọ́n àńgẹ́lì náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Màríà: nítorí ìwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
31 Ìwọ óò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní JÉSÙ.
32 Òun ó pọ̀, Ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é: Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún:
33 Yóò sì jọba lórí ilé Jákọ́bù títí láé; ìjọba rẹ̀ kì yóò sì ní ìpẹ̀kun.”
34 Nígbà náà ni Màríà bèèrè lọ́wọ́ ańgẹ́lì náà pé, “Èyí yóò ha ti ṣe rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí èmi kò tii mọ ọkùnrin.”