50 Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀láti ìrandíran.
51 Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀;Ó ti tú àwọn onígberaga ká ní ìrònú ọkàn wọn.
52 Ó ti mú àwọn alágbára kúrò lórí ìtẹ́ wọn,Ó sì gbé àwọn onírẹ̀lè lékè.
53 Ó ti fi ohun tí ó dára kún àwọn tí ebí ń paó sì rán àwọn ọlọ́rọ̀ padà ní òfo.
54 Ó ti ran Ísíráẹ́lì ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́,Ní ìrántí àánú rẹ̀;
55 sí Ábúráhámù àti àwọn ìran rẹ̀ láéláé, baba wa,àti bí ó ti sọ fún àwọn baba wa.”
56 Màríà sì jókòó tì Èlísábétì níwọ̀n oṣù mẹ́ta, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀.