65 Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ń bẹ ní agbègbè wọn: a sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí ká gbogbo ilẹ̀ òkè Jùdéà.
66 Ó sì jẹ́ ohun ìyọnu fún gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n ń wí pé, “Irú ọmọ kínni èyí yóò jẹ́?” Nítirí tí ọwọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.
67 Sakaráyà baba rẹ̀ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì ṣọtẹ́lẹ̀, ó ní:
68 “Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì;Nítorí tí ó ti bojúwò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè,
69 Ó sì ti gbé ìwo ìgbàlà sókè fún waNí ilé Dáfídì ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀;
70 (bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ ní ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ típẹ́típẹ́),
71 Pé, a ó gbà wá là lọ́wọ́àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ àwọn tí ó kórira wá;