69 Ó sì ti gbé ìwo ìgbàlà sókè fún waNí ilé Dáfídì ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀;
70 (bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ ní ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ típẹ́típẹ́),
71 Pé, a ó gbà wá là lọ́wọ́àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ àwọn tí ó kórira wá;
72 Láti ṣe àánú tí ó ti lérí fún àwọn baba wa,Àti láti rántí májẹ̀mu rẹ̀ mímọ́,
73 ìbúra tí ó ti bú fún Ábúráhámù baba wa,
74 láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,Kí àwa kí ó lè máa sìn ín láìfòyà,
75 Ní mímọ́ ìwà àti ní òdodo níwájú rẹ̀, ní ọjọ́ ayé wa gbogbo.