75 Ní mímọ́ ìwà àti ní òdodo níwájú rẹ̀, ní ọjọ́ ayé wa gbogbo.
76 “Àti ìwọ, ọmọ mi, wòlíì Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó máa pè ọ́:Nítorí ìwọ ni yóò ṣáájú Olúwa láti tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe;
77 Láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn ènìyàn rẹ̀fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
78 nítorí ìyọ́nú Ọlọ́run wà;nípa èyí tí ìlà-òrùn láti òkè wá bojúwò wá,
79 Láti fi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó jókòó níòkùnkùn àti ní òjìjì ikú.Àti láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà àlààáfíà.”
80 Ọmọ náà sì dàgbà, ó sì le ní ọkàn, ó sì ń gbé ní ijù títí ó fi di ọjọ́ ìfihàn rẹ̀ fún Ísírẹ́lì.