1 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn míràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjìméjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkárarẹ̀ yóò sì dé.
2 Ó sì wí fún wọn pé, “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan, nítorí náà ẹ bẹ Olúwa ìkórè, kí ó lè rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.
3 Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n: sá wò ó, èmi rán yín lọ bí ọ̀dọ́ àgùntàn sáàrin ìkookò.
4 Ẹ má ṣe mú àpò, ẹ má ṣe mú àpamọ́wọ́, tàbí bàtà: ẹ má sì ṣe kí ẹnikẹ́ni lọ́nà.
5 “Ní ilékílé tí ẹ̀yín bá wọ̀, kí ẹ kọ́ wí pé, ‘Àlààáfíà fún ilé yìí!’