13 “Ègbé ni fún ìwọ, Kórásínì! Ègbé ni fún ìwọ Bẹtiṣáídà! Nítorí ìbáṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ agbára tí a ṣe nínú yín, ní Tírè àti Ṣídónì, wọn ìbá ti ronúpìwàdà lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, wọn ìbá sì jókòó nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti nínú eérú.
14 Ṣùgbọ́n yóò sàn fún Tírè àti Sídónì nígbà ìdájọ́ jù fún yín lọ.
15 Àti ìwọ, Kápánáúmù, a ó ha gbé ọ ga dé òkè ọ̀run? A ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ dé isà òkú.
16 “Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi: ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.”
17 Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”
18 Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Sátánì ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá.
19 Kíyèsí i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèé mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì sí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára.