14 Ṣùgbọ́n yóò sàn fún Tírè àti Sídónì nígbà ìdájọ́ jù fún yín lọ.
15 Àti ìwọ, Kápánáúmù, a ó ha gbé ọ ga dé òkè ọ̀run? A ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ dé isà òkú.
16 “Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi: ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.”
17 Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”
18 Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Sátánì ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá.
19 Kíyèsí i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèé mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì sí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára.
20 Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ sí èyí, pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé; a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run!”