17 Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”
18 Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Sátánì ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá.
19 Kíyèsí i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèé mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì sí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára.
20 Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ sí èyí, pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé; a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run!”
21 Ní wákàtí kan náà Jésù yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́: bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sáà yẹ ní ojú rẹ.
22 “Ohun gbogbo ni a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Baba mi; kò sì sí ẹni tí ó mọ ẹni tí ọmọ jẹ́, bí kò ṣe Baba; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wu ọmọ láti fi í hàn fún.”
23 Ó sì yípadà sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní apákan. Ó ní, “Ìbùkún ni fún ojú tí ń rí ohun tí ẹ̀yin ń rí.