2 Ó sì wí fún wọn pé, “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan, nítorí náà ẹ bẹ Olúwa ìkórè, kí ó lè rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.
3 Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n: sá wò ó, èmi rán yín lọ bí ọ̀dọ́ àgùntàn sáàrin ìkookò.
4 Ẹ má ṣe mú àpò, ẹ má ṣe mú àpamọ́wọ́, tàbí bàtà: ẹ má sì ṣe kí ẹnikẹ́ni lọ́nà.
5 “Ní ilékílé tí ẹ̀yín bá wọ̀, kí ẹ kọ́ wí pé, ‘Àlààáfíà fún ilé yìí!’
6 Bí ọmọ àlààáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e: ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò tún padà sọ́dọ̀ yín.
7 E dúró sínú ilé yẹn, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fifún yín; nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i, Ẹ má ṣe ṣí láti ilé dé ilé.
8 “Ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọ́n bá sì gbà yín, ẹ jẹ ohunkóhun tí a bá gbé ka iwájú yín: