24 Nítorí mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba ni ó ń fẹ́ láti rí ohun tí ẹ̀yin ń rí, wọn kò sì rí wọn, àti láti gbọ́ ohun tí ẹ̀yin ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.”
25 Sì kíyèsí i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, “Olùkọ́, kínni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”
26 Ó sì bi í pé, “Kí ni a kọ sínú ìwé òfin? Bí ìwọ ti kà á?”
27 Ó sì dáhùn wí pé, “ ‘Kí ìwọ fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ’; àti, ‘Ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ ”
28 Ó sì wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn rere: ṣe èyí, ìwọ ó sì yè.”
29 Ṣùgbọ́n ó ń fẹ́ láti da ara rẹ̀ láre, ó wí fún Jésù wí pé, “Ta ha sì ni ẹnìkejì mi?”
30 Jésù sì dáhùn ó wí pé, “Ọkùnrin kan ń ti Jerúsálémù sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán.