35 Nígbà tí ó sì lọ ní ijọ́ kejì, ó fi owó idẹ méjì fún olórí ilé èrò ó sì wí fún un pé, ‘Má a tọ́jú rẹ̀; ohunkóhun tí ìwọ bá sì ná kún un, nígbà tí mo bá padà dé, èmi ó san án fún ọ.’
36 “Nínú àwọn mẹ́tẹ̀èta wọ̀nyí, tani ìwọ rò pé ó jẹ́ ẹnìkejì ẹni tí ó bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà?”
37 Ó sì dáhùn wí pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un.”Jésù sì wí fún un pé, “Lọ, kí o ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́!”
38 Ó sì se, bí wọ́n ti ń lọ, o wọ ìletò kan, obìnrin kan tí a ń pè ní Mátà sì gbà á sí ilé rẹ̀.
39 Ó sì ní arábìnrin kan tí a ń pè ní Màríà tí ó sì jókòó lẹ́bàá ẹṣẹ̀ Jésù, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
40 Ṣùgbọ́n Mátà ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkàn ṣe ìránṣẹ́? Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́.”
41 Ṣùgbọ́n Jésù sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Mátà, Mátà, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀.