5 “Ní ilékílé tí ẹ̀yín bá wọ̀, kí ẹ kọ́ wí pé, ‘Àlààáfíà fún ilé yìí!’
6 Bí ọmọ àlààáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e: ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò tún padà sọ́dọ̀ yín.
7 E dúró sínú ilé yẹn, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fifún yín; nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i, Ẹ má ṣe ṣí láti ilé dé ilé.
8 “Ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọ́n bá sì gbà yín, ẹ jẹ ohunkóhun tí a bá gbé ka iwájú yín:
9 Ẹ sì mú àwọn aláìsàn tí ń bẹ nínú rẹ̀ láradá, kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀ sí yín!’
10 Ṣùgbọ́n ní ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, tí wọn kò bá sì gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá sì jáde sí ìgboro ìlú náà, kí ẹ̀yin sì wí pé,
11 ‘Eruku ìlú yín tí ó kù sí wa lẹ́sẹ̀, a gbọ̀n ọ́n sílẹ̀ fún yín! Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, ìjọba Ọlọ́run kù dẹ̀dẹ̀ sí yín!’