Lúùkù 11:27-33 BMY

27 Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, obìnrin kan nahùn rẹ̀ sókè nínú ìjọ, ó sì wí fún un pé, “Ìbùkún ni fún inú tí ó bí ọ, àti ọmú tí ìwọ mu!”

28 Ṣùgbọ́n oun wí pé, Nítòótọ́, kí ó kúkú wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì pa á mọ́!”

29 Nígbà tí ìjọ ènìyàn sì ṣùjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, “Ìran búburú ni èyí: wọ́n ń wá àmì; a kì yóò sì fi àmì kan fún un bí kò ṣe àmì Jónà wòlíì!

30 Nítorí bí Jónà ti jẹ́ àmì fún àwọn ará Nínéfè, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọmọ-ènìyàn yóò ṣe jẹ́ àmì fún ìran yìí.

31 Ọba-bìnrin gúsù yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìran yìí, yóò sì dá wọn lẹ́bi: nítorí tí ó ti ìhà ìpẹ̀kun ayé wá láti gbọ́ ọgbọ́n Sólómónì: sì kíyèsí i, ẹni tí ó pọ̀ju Sólómónì lọ ń bẹ níhín-ín yìí.

32 Àwọn ará Nínéfè yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, wọn ó sì dá a lẹ́bi: nítorí tí wọn ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jónà; sì kíyèsíi, ẹni tí ó pọ̀jù Jónà lọ ń bẹ níhín-ín yìí.

33 “Kò sí ẹnìkan, nígbà tí ó bá tan fìtílà tan, tí i gbé e sí ìkọ̀kọ̀, tàbí sábẹ́ òṣùwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọlé baà lè má a rí ìmọ́lẹ̀.