30 Nítorí bí Jónà ti jẹ́ àmì fún àwọn ará Nínéfè, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọmọ-ènìyàn yóò ṣe jẹ́ àmì fún ìran yìí.
31 Ọba-bìnrin gúsù yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìran yìí, yóò sì dá wọn lẹ́bi: nítorí tí ó ti ìhà ìpẹ̀kun ayé wá láti gbọ́ ọgbọ́n Sólómónì: sì kíyèsí i, ẹni tí ó pọ̀ju Sólómónì lọ ń bẹ níhín-ín yìí.
32 Àwọn ará Nínéfè yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, wọn ó sì dá a lẹ́bi: nítorí tí wọn ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jónà; sì kíyèsíi, ẹni tí ó pọ̀jù Jónà lọ ń bẹ níhín-ín yìí.
33 “Kò sí ẹnìkan, nígbà tí ó bá tan fìtílà tan, tí i gbé e sí ìkọ̀kọ̀, tàbí sábẹ́ òṣùwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọlé baà lè má a rí ìmọ́lẹ̀.
34 Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara: bí ojú rẹ bá mọ́, gbogbo ara rẹ a mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá burú, ara rẹ pẹ̀lú a kún fún òkùnkùn.
35 Nítorí náà kíyèsí i, kí ìmọ́lẹ̀ tí ń bẹ nínú rẹ má ṣe di òkùnkùn.
36 Ǹjẹ́ bí gbogbo ara rẹ bá kún fún ìmọ́lẹ̀, tí kò ní apákan tí ó ṣókùnkùn, gbogbo rẹ̀ ni yóò ní ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí fìtílà bá fi ìtànsán rẹ̀ fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”