36 Ǹjẹ́ bí gbogbo ara rẹ bá kún fún ìmọ́lẹ̀, tí kò ní apákan tí ó ṣókùnkùn, gbogbo rẹ̀ ni yóò ní ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí fìtílà bá fi ìtànsán rẹ̀ fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”
37 Bí ó sì ti ń wí, Farisí kan bẹ̀ẹ́ kí ó bá òun jẹun: ó sì wọlé, ó jókòó láti jẹun.
38 Nígbà tí Farisí náà sì rí i, ẹnu yà á nítorí tí kò kọ́kọ́ wẹ ọwọ́ kí ó tó jẹun
39 Olúwa sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin Farisí a máa fẹ́ fi ara hàn bí ènìyàn mímọ́ ṣùgbọ́n, inú yín kún fún ìwà búburú àti ìrẹ́jẹ.
40 Ẹ̀yin aláìmòye, ẹni tí ó ṣe èyí tí ń bẹ lóde, òun kò ha ṣe èyí tí ń bẹ nínú pẹ̀lú?
41 Kí ẹ̀yin kúkú má a ṣe ìtọrẹ àánú nínú ohun tí ẹ̀yin ní, sì kíyèsii, ohun gbogbo ni ó di mímọ́ fún yín.
42 “Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisí, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá mítì àti rue, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsì fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe.