1 Àwọn kan sì wá ní àkókò náà tí ó sọ ti àwọn ará Gálílì fún un, ẹ̀jẹ̀ ẹni tí Pílátù dàpọ̀ mọ́ ti wọn.
2 Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ṣe bí àwọn ará Gálílì wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ará Gálílì lọ, nítorí wọ́n jẹ iru ìyà báwọ̀n-ọ́n-nì?
3 Mo wí fún yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́: bí kò se pé ẹ̀yin ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.
4 Tàbí àwọn méjìdínlógún, tí ilé-ìsọ́ ní Sílóámù wólù, tí ó sì pa wọ́n, ẹ̀yin sebí wọ́n ṣe ẹlẹ́sẹ̀ ju gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní Jerúsálémù lọ?