18 “Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ ní ohùn kan láti ṣe àwáwí. ‘Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’
19 “Èkejì sì wí pé, ‘Mo ra màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’
20 “Ẹ̀kẹ́ta sì wí pé, ‘Mo sẹ̀sẹ̀ gbéyàwó, nítorí náà ni èmi kò fi lè wá.’
21 “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì padà dé, ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún olúwa rẹ̀. Nígbà náà ni baálé ilé bínú, ó wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Jáde lọ sí ìgboro, àti sí òpòpò ọ̀nà, kí o sì mú àwọn tálákà, àti àwọn amúkùn-ún, àti àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú wá sí ìhín yìí.’
22 “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì wí pé, ‘Olúwa a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, àyè sì ń bẹ síbẹ̀.’
23 “Olúwa náà sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà pé, ‘Jáde lọ sí òpópó, àti sí ọ̀nà ọgbà, kí o sì rọ̀ wọ́n láti wọlé wá, kí ilé mi lè kún.
24 Nítorí mo wí fún yín, Ẹnìkẹ́ni nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí a ti pè, kì yóò tọ́ wò nínú àsè ńlá mi!’ ”