32 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà tí onítọ̀hún bá sì wà ní òkèrè, òun a rán ikọ̀ sí i, a sì bẹ̀rẹ̀ àdéhùn àlààáfíà.
33 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó ṣe nínú yín, tí kò kọ ohun gbogbo tí ó ní sílẹ̀, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.
34 “Iyọ̀ dára: ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu, kínni a ó fi mú un dùn?
35 Kò yẹ fún ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ fún ààtàn; bí kò ṣe pé kí a kó o dànù.“Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”