13 “Kò sí ìránṣẹ́ kan tí ó le sin olúwa méjì: àyàfi kí ó kórìíra ọ̀kan, yóò sì fẹ́ èkejì; tàbí yóò fi ara mọ́ ọ̀kan yóò sì yan èkejì ní ìpọ̀sì. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run pẹ̀lú mámónì.”
14 Àwọn Farisí, tí wọ́n ní ojúkòkòrò sì gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì yọ sùtì sí i.
15 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni àwọn tí ń dáre fún ara yín níwájú ènìyàn; ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ ọkàn yín: nítorí èyí tí a gbé níyìn lọ́dọ̀ ènìyàn, ìríra ni níwájú Ọlọ́run.
16 “Òfin àti àwọn wòlíì ń bẹ títí di ìgbà Jòhánù: Láti ìgbà náà wá ni a ti ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, olúkúlùkù sì ń fi ipá wọ inú rẹ̀.
17 Ṣùgbọ́n ó rọrùn fún ọ̀run òun ayé láti kọjá lọ, ju kí sóńsó kan ti òfin kí ó yẹ̀.
18 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbé òmíràn ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà: ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé, ẹni tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà.
19 “Ǹjẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ń wọ asọ elésèé àlùkò àti asọ àlà dáradára, a sì máa jẹ dídùndídùn lójóojúmọ́: