27 “Ó sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ mo bẹ̀ ọ́, baba, kí ìwọ kí ó rán an lọ sí ilé baba mi:
28 Nítorí mo ní arákùnrin márùnún; kí ó lè rò fún wọn kí àwọn kí ó má baa wá sí ibi oró yìí pẹ̀lú.’
29 “Ábúráhámù sì wí fún un pé, ‘Wọ́n ní Mósè àti àwọn wòlíì; kí wọn kí ó gbọ́ ti wọn.’
30 “Ó sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, Ábúráhámù baba; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ti inú òkú tọ̀ wọ́n lọ, wọn ó ronúpìwàdà.’
31 “Ó sì wí fún un pé, ‘Bí wọn kò bá gbọ́ ti Mósè àti ti àwọn wòlíì, a kì yóò yí wọn ní ọkàn padà bí ẹnìkan tilẹ̀ ti inú òkú dìde.’ ”