1 Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kò le ṣe kí ohun ìkọ̀sẹ̀ máa dé: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí ó ti ipaṣẹ̀ rẹ̀ dé.
2 Ìbá sàn fún un kí a so ọlọ mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì gbé e jù sínú òkun, ju kí ó mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀
3 Ẹ máa kíyèsíra yín.“Bí arákùnrin rẹ bá sẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dárí jìn ín.
4 Bí ó bá sì sẹ̀ ọ́ ní ẹ̀rìnméje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ẹ̀rẹ̀méje ní òòjọ́ pé, ‘Mo ronúpìwàdà,’ dárí jìn ín.”