4 Bí ó bá sì sẹ̀ ọ́ ní ẹ̀rìnméje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ẹ̀rẹ̀méje ní òòjọ́ pé, ‘Mo ronúpìwàdà,’ dárí jìn ín.”
5 Àwọn àpósítélì sì wí fún Olúwa pé, “Bùsí ìgbàgbọ́ wa.”
6 Olúwa sì wí pé, “Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bí hóró irúgbìn músítadì, ẹ̀yin yóò lè wí fún igi Músítádì yìí pé, ‘Kí a fà á tu, kí a sì gbìn ọ́ sínú òkun,’ yóò sì gbọ́ ti yín.
7 “Ṣùgbọ́n tani nínú yín, tí ó ní ọmọ ọ̀dọ̀, tí ó ń tulẹ̀, tàbí tí ó ń bọ́ ẹran, tí yóò wí fún un lójú kan náà tí ó bá ti oko dé pé, ‘Lọ í jòkòó láti jẹun’?
8 Tí kì yóò kúkú wí fún un pé, ‘Pèsè ohun tí èmi yóò jẹ, sì di àmùrè, kí ìwọ kí ó máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi, títí èmi ó fi jẹ kí èmi ó sì mu tán; lẹ́yìn náà ni ìwọ ó sì jẹ, tí ìwọ ó sì mu’?
9 Òun ó ha máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nítorí ó ṣe ohun tí a pa láṣẹ fún un bí? Èmi kò rò bẹ́ẹ̀.
10 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pàṣẹ fún yín tán, ẹ wí pé, ‘Aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀ ni wá: èyí tí í se iṣẹ́ wa láti ṣe, ní àwá ti ṣe.’ ”