11 Èyí Farisí dìde, ó sì ń gbàdúrà nínú ara rẹ̀ báyìí pé, ‘Ọlọ́run mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí èmi kò rí bí àwọn ará ìyókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòótọ́, panṣágà, tàbí bí agbowó òde yìí.
12 Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì lọ́ṣẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní.’
13 “Ṣùgbọ́n agbowó òde dúró lókèrè, kò tilẹ̀ jẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ṣùgbọ́n ó lu ara rẹ̀ ní oókan àyà, ó wí pé, ‘Ọlọ́run ṣàánú fún mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀!’
14 “Mo wí fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ìdáláre ju èkejì lọ: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, òun ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá sì rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ òun ni a ó gbéga.”
15 Wọ́n sì gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú, kí ó lè fi ọwọ́ lé wọn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí i, wọ́n ń bá wọn wí.
16 Ṣùgbọ̀n Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun: nítorí tí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run.
17 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbà ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.”