14 “Mo wí fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ìdáláre ju èkejì lọ: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, òun ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá sì rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ òun ni a ó gbéga.”
15 Wọ́n sì gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú, kí ó lè fi ọwọ́ lé wọn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí i, wọ́n ń bá wọn wí.
16 Ṣùgbọ̀n Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun: nítorí tí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run.
17 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbà ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.”
18 Ìjòyè kan sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, wí pé, “Olùkọ́ rere, kínni èmi ó ṣe tí èmi ó fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”
19 Jésù wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí bí kò ṣe ẹnìkan, èyí sì ni Ọlọ́run.
20 Ìwọ mọ̀ àwọn òfin, ‘Má ṣe ṣe panṣágà, má ṣe pànìyàn, má ṣe jalè, má ṣe jẹ́rìí èké, bọ̀wọ̀ fún bàbá àti ìyá rẹ.’ ”