17 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbà ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.”
18 Ìjòyè kan sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, wí pé, “Olùkọ́ rere, kínni èmi ó ṣe tí èmi ó fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”
19 Jésù wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí bí kò ṣe ẹnìkan, èyí sì ni Ọlọ́run.
20 Ìwọ mọ̀ àwọn òfin, ‘Má ṣe ṣe panṣágà, má ṣe pànìyàn, má ṣe jalè, má ṣe jẹ́rìí èké, bọ̀wọ̀ fún bàbá àti ìyá rẹ.’ ”
21 Ó sì wí pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti pa mọ́ láti ìgbà èwe mi wá.”
22 Nígbà tí Jésù sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, “Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn talákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra lọ́run: sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
23 Nígbà tí ó sì gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi: nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.