1 Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àṣẹ ti ọ̀dọ̀ Késárì Ògọ́sítù jáde wá pé, kí a kọ orúkọ gbogbo ìjọba Rosínú ìwé.
2 (Èyí ni ìkọ sínú ìwé ìkínní tí a ṣe nígbà tí Kíréníyù fi jẹ Baálẹ̀ Síríà.)
3 Gbogbo àwọn ènìyàn sì lọ láti kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé, olúkúlùkù sí ìlú ara rẹ̀.
4 Jóṣéfù pẹ̀lú sì gòkè láti Násárẹ́tì ìlú Gálílì, sí ìlú Dáfídì ní Jùdéà, tí à ń pè ní Bétílẹ́hẹ́mù; nítorí ti ìran àti ìdílé Dáfídì ní í ṣe,
5 Láti kọ orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú Màríà aya rẹ̀ àfẹ́sọ́nà, tí oyún rẹ̀ tí tó bi.
6 Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ pé tí òun óò bí.
7 Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran; nítorí tí àyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò.