22 Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó-òde fún Késárì, tàbí kò tọ́?”
23 Ṣùgbọ́n ó kíyèsí àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé,
24 “Ẹ fi owó-idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti tani ó wà níbẹ̀?”
25 Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Késárì ni.”Ó sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Késárì fún Késárì, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”
26 Wọn kò sì lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú níwájú àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn rẹ̀, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́.
27 Àwọn Ṣadusí kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí: wọ́n sì bi í,
28 Wí pé, “Olùkọ́, Mósè kọ̀wé fún wa pé: Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀.