38 Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè: nítorí gbogbo wọn wà láàyè fún un.”
39 Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé dá a lóhùn, pé, “Olùkọ́ ìwọ wí rere!”
40 Wọn kò sì jẹ́ bi í léèrè ọ̀rọ̀ kan mọ́.
41 Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí wọ́n fi ń wí pé, Ọmọ Dáfídì ni Kírísítì?
42 Dáfídì tìkárarẹ̀ sì wí nínú ìwé Psalmu pé:“ ‘JÈHÓFÀ wí fún Olúwa mi pé:“Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
43 Títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹdi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’
44 Ǹjẹ́ bí Dáfídì bá pè é ní ‘Olúwa.’ Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”