43 Títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹdi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’
44 Ǹjẹ́ bí Dáfídì bá pè é ní ‘Olúwa.’ Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
45 Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní etí gbogbo ènìyàn pé,
46 “Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn ní aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú sínágọ́gù, àti ipò ọlá ní ibi àsè;
47 Àwọn tí ó jẹ ilé àwọn opó run, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn: àwọn wọ̀nyí náà ni yóò jẹ̀bi pọ̀jù.”