9 Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òwe yìí fún àwọn ènìyàn pé: “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùsọ́gbà, ó sì lọ sí àjò fún ìgbà pípẹ́.
10 Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùsọ́gbà náà: kí wọn lè fún un nínú èṣo ọgbà àjàrà náà: ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.
11 Ó sì tún rán ọmọ-ọ̀dọ̀ míràn: wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ níyà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.
12 Ó sì tún rán ẹ̀kẹ́ta: wọ́n sì ṣá a lọ́gbẹ́ pẹ̀lú, wọ́n sì tì í jáde.
13 “Nígbà náà ni Olúwa ọgbà àjàrà wí pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Èmi ó rán ọmọ mi àyànfẹ́ lọ: bóyá nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn ó ṣojúsájú fún un.’
14 “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn alágbàtọ́jú náà rí i, wọ́n bá ara wọn gbérò pé, ‘Èyí ni àrólé; ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún rẹ̀ lè jẹ́ ti wa.’
15 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tìí jáde sẹ́yìn ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á.“Ǹjẹ́ kínni olúwa ọgbà àjàrà náà yóò ṣe sí wọn?