10 Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba.
11 Ilẹ̀ríri ilẹ̀ ńlá yóò sì wà káàkiri, àti ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn; ohun ẹ̀rù, àti àmì ńlá yóò sì ti ọ̀run wá.
12 “Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí sínágọ́gù, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi.
13 Yóò sì padà di ẹ̀rí fún yín.
14 Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ lọ́kàn yín pé ẹ yóò ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn.
15 Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú.
16 A ó sì fi yín hàn láti ọwọ́ àwọn òbí yín wá, àti àwọn arákùnrin, àti àwọn ìbátan, àti àwọn ọ̀ré; on ó sì mú kì a pa nínú yín.