27 Nígbà náà ni wọn ó sì rí ọmọ-ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú ìkùukù àwọ̀sánmà pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.
28 Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.”
29 Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ẹ kíyèsí igi ọ̀pọ̀tọ́, àti sí gbogbo igi;
30 Nígbà tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin rí i, ẹ sì mọ̀ fúnrarayín pé, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kù fẹ́rẹ́fẹ́.
31 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, nígbà tí ẹ̀yin bá rí nǹkan wọ̀nyí tí o sẹ, kí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.
32 “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ìran yìí kì yóò rékọjá, títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ.
33 Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.