13 Wọ́n sì lọ wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó tí sọ fún wọn: wọ́n sì pèsè ìrékọjá sílẹ̀.
14 Nígbà tí àkókò sì tó, ó jókòó àti àwọn àpósítélì pẹ̀lú rẹ̀.
15 Ó sì wí fún wọn pé, “Tinú-tinú ni èmi fẹ́ fi bá yín jẹ ìrékọjá yìí, kí èmi tó jìyà:
16 Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò jẹ nínú rẹ̀ mọ́, títí a ó fi mú un ṣẹ ní ìjọba Ọlọ́run.”
17 Ó sì gba aago, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó wí pé, “Gba èyí, kí ẹ sì pín in láàrin ara yín.
18 Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò mu nínú èso àjàrà mọ́, títí ìjọba Ọlọ́run yóò fi dé.”
19 Ó sì mú àkàrà, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́ ó bù ú, ó sì fifún wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yí ni ara mí tí a fifún yín: ẹ má a ṣe èyí ní ìrántí mi.”