34 Ó sì wí pé, “Mo wí fún ọ, Pétérù, àkùkọ kì yóò kọ lónìí-ín tí ìwọ ó fi sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, ìwọ kò mọ̀ mí.”
35 Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí mo rán yín lọ láìní àpò-owó, àti àpò, àti bàtà, ọ̀dá ohun kan dá yín bí?”Wọ́n sì wí pé, “Rárá!”
36 Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹni tí ó bá ní àpò owó kí ó mú un, àti àpò pẹ̀lú; ẹni tí kò bá sì ní idà, kí ó ta aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi ra ìkan.
37 Nítorí mo wí fún yín pé, ‘Èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ lára mi, A sì kà á mọ́ àwọn arúfin.’ Nítorí àwọn ohun wọ̀nyí nípa ti èmi yóò ní ìmúṣẹ.”
38 Wọ́n sì wí pé, “Olúwa, sá wò ó, idà méjì ń bẹ níhín-ín yìí!”Ó sì wí fún wọn pé, “Ó tó.”
39 Ó sì jáde, ó sì lọ bí ìṣe rẹ̀ sí òkè ólífì, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
40 Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwọ̀.”