1 Gbogbo ìjọ ènìyàn sì dìde, wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ Pílátù.
2 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án, wí pé, “Àwa rí ọkùnrin yìí ó ń yí orílẹ̀-èdè wa lọ́kàn padà, ó sì ń dá wọn lẹ́kun láti san owó-òde fún Késárì, ó ń wí pé, òun tìkara-òun ni Kírísítì ọba.”
3 Pílátù sì bi í léèrè, wí pé, “Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù?”Ó sì dá a lóhùn wí pé, “Ìwọ wí i.”
4 Pílátù sì wí fún àwọn Olórí àlùfáà àti fún ìjọ ènìyàn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ Ọkùnrin yìí.”