11 Àti Hẹ́rọ́dù pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì ń fi í ṣẹ̀sín, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ dáradára, ó sì rán an padà tọ Pílátù lọ.
12 Pílátù àti Hẹ́rọdù di ọ̀rẹ́ ara wọn ní ijọ́ náà: nítorí látijọ́ ọ̀tá ara wọn ni wọ́n ti jẹ́ rí.
13 Pílátù sì pe àwọn olórí àlúfáà àti àwọn olórí àti àwọn ènìyàn jọ.
14 Ó sọ fún wọn pé, “Ẹyin mú ọkùnrin yìí tọ̀ mí wá, bí ẹni tí ó ń yí àwọn ènìyàn ní ọkàn padà: sì kíyèsí i, èmí wádìí ẹjọ́ rẹ̀ níwájú yín èmi kò sì rí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ ọkùnrin yìí, ní gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ẹ̀yin fi ẹ̀sùn rẹ̀ sùn.
15 Àti Hẹ́rọ́dù pẹ̀lú; ó sá rán an padà tọ̀ wá wá; sì kíyèsí i, ohun kan tí ó yẹ sí ikú ni a kò ṣe láti ọwọ́ rẹ̀.
16 Ǹjẹ́ èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀ lọ.”
17 (Ṣùgbọ́n kò lè ṣàì dá ọ̀kan sílẹ̀ fún wọn nígba àjọ ìrékọjá.)