13 Pílátù sì pe àwọn olórí àlúfáà àti àwọn olórí àti àwọn ènìyàn jọ.
14 Ó sọ fún wọn pé, “Ẹyin mú ọkùnrin yìí tọ̀ mí wá, bí ẹni tí ó ń yí àwọn ènìyàn ní ọkàn padà: sì kíyèsí i, èmí wádìí ẹjọ́ rẹ̀ níwájú yín èmi kò sì rí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ ọkùnrin yìí, ní gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ẹ̀yin fi ẹ̀sùn rẹ̀ sùn.
15 Àti Hẹ́rọ́dù pẹ̀lú; ó sá rán an padà tọ̀ wá wá; sì kíyèsí i, ohun kan tí ó yẹ sí ikú ni a kò ṣe láti ọwọ́ rẹ̀.
16 Ǹjẹ́ èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀ lọ.”
17 (Ṣùgbọ́n kò lè ṣàì dá ọ̀kan sílẹ̀ fún wọn nígba àjọ ìrékọjá.)
18 Wọ́n sì kígbe sókè nígbà kan náà, pé, “Mú ọkùnrin yìí kúrò, kí o sì dá Bárábà sílẹ̀ fún wa!”
19 Ẹni tí a sọ sínú túbú nítorí ọ̀tẹ̀ kan tí a ṣe ní ìlú, àti nítorí ìpànìyàn.