16 Ǹjẹ́ èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀ lọ.”
17 (Ṣùgbọ́n kò lè ṣàì dá ọ̀kan sílẹ̀ fún wọn nígba àjọ ìrékọjá.)
18 Wọ́n sì kígbe sókè nígbà kan náà, pé, “Mú ọkùnrin yìí kúrò, kí o sì dá Bárábà sílẹ̀ fún wa!”
19 Ẹni tí a sọ sínú túbú nítorí ọ̀tẹ̀ kan tí a ṣe ní ìlú, àti nítorí ìpànìyàn.
20 Pílátù sì tún bá wọn sọ̀rọ̀, nítorí ó fẹ́ dá Jésù sílẹ̀.
21 Ṣùgbọ́n wọ́n kígbe, wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélèbú, kàn án mọ àgbélèbú!”
22 Ó sì wí fún wọn lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, “Èéṣe, búburú kínni ọkùnrin yìí ṣe? Èmi kò rí ọ̀ràn ikú lára rẹ̀: nítorí náà èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀.”