22 Ó sì wí fún wọn lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, “Èéṣe, búburú kínni ọkùnrin yìí ṣe? Èmi kò rí ọ̀ràn ikú lára rẹ̀: nítorí náà èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀.”
23 Wọ́n túbọ̀ tẹramọ́ igbe ńlá, wọ́n ń fẹ́ kí a kàn án mọ́ àgbélèbú, Ohùn tiwọn àti ti àwọn olórí àlùfáà borí tirẹ̀.
24 Pílátù sí fi àṣẹ sí i pé, kí ó rí bí wọ́n ti ń fẹ́.
25 Ó sì dá ẹni tí wọ́n fẹ́ sílẹ̀ fún wọn, ẹni tí a tìtorí ọ̀tẹ̀ àti ìpànìyàn sọ sínú túbú; ṣùgbọ́n ó fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.
26 Bí wọ́n sì ti ń fà á lọ, wọ́n mú ọkùnrin kan, Símónì ara Kírénè, tí ó ń ti ìgbéríko bọ̀, òun ni wọ́n sì gbé àgbélèbú náà lé, kí ó máa rù ú lọ tẹ̀lé Jésù.
27 Ìjọ ènìyàn púpọ̀ ni ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, àti àwọn obìnrin, tí ń pohùnréré ẹkún
28 Ṣùgbọ̀n Jésù yíjú padà sí wọn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálémù, ẹ má sọkún fún mi, ṣùgbọ́n ẹ sọkún fún ara yín, àti fún àwọn ọmọ yín.