24 Pílátù sí fi àṣẹ sí i pé, kí ó rí bí wọ́n ti ń fẹ́.
25 Ó sì dá ẹni tí wọ́n fẹ́ sílẹ̀ fún wọn, ẹni tí a tìtorí ọ̀tẹ̀ àti ìpànìyàn sọ sínú túbú; ṣùgbọ́n ó fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.
26 Bí wọ́n sì ti ń fà á lọ, wọ́n mú ọkùnrin kan, Símónì ara Kírénè, tí ó ń ti ìgbéríko bọ̀, òun ni wọ́n sì gbé àgbélèbú náà lé, kí ó máa rù ú lọ tẹ̀lé Jésù.
27 Ìjọ ènìyàn púpọ̀ ni ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, àti àwọn obìnrin, tí ń pohùnréré ẹkún
28 Ṣùgbọ̀n Jésù yíjú padà sí wọn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálémù, ẹ má sọkún fún mi, ṣùgbọ́n ẹ sọkún fún ara yín, àti fún àwọn ọmọ yín.
29 Nítorí kíyèsí i, ọjọ́ ń bọ̀ ní èyí tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Ìbùkún ni fún àgàn, àti fún inú tí kò bímọ rí, àti fún ọmú tí kò fúnni mu rí!’
30 Nígbà náà ni“ ‘wọn ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn òkè kékèké pé,“Bò wá mọ́lẹ̀!” ’