29 Nítorí kíyèsí i, ọjọ́ ń bọ̀ ní èyí tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Ìbùkún ni fún àgàn, àti fún inú tí kò bímọ rí, àti fún ọmú tí kò fúnni mu rí!’
30 Nígbà náà ni“ ‘wọn ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn òkè kékèké pé,“Bò wá mọ́lẹ̀!” ’
31 Nítorí bí wọn bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí sára igi tútù, kínni a ó ṣe sára gbígbẹ?”
32 Àwọn méjì mìíràn bákàn náà, àwọn arúfin, ni wọ́n sì fà lọ pẹ̀lú rẹ̀ láti pa.
33 Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí, níbẹ̀ ni wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélèbú, àti àwọn arúfin náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti ọ̀kan ní ọwọ́ òsì.
34 Jésù sì wí pé, “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí tí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” Wọ́n di ìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrin ara wọn.
35 Àwọn ènìyàn sì dúró ń wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kírísítì, àyànfẹ́ Ọlọ́run.”