32 Àwọn méjì mìíràn bákàn náà, àwọn arúfin, ni wọ́n sì fà lọ pẹ̀lú rẹ̀ láti pa.
33 Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí, níbẹ̀ ni wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélèbú, àti àwọn arúfin náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti ọ̀kan ní ọwọ́ òsì.
34 Jésù sì wí pé, “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí tí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” Wọ́n di ìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrin ara wọn.
35 Àwọn ènìyàn sì dúró ń wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kírísítì, àyànfẹ́ Ọlọ́run.”
36 Àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ń fi ọtí kíkan fún un.
37 Wọ́n sì ń wí pé, “Bí ìwọ́ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.”
38 Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Gíríkì, àti ti Látínì, àti tí Hébérù: ÈYÍ NI ỌBA ÀWỌN JÚÙ.