37 Wọ́n sì ń wí pé, “Bí ìwọ́ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.”
38 Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Gíríkì, àti ti Látínì, àti tí Hébérù: ÈYÍ NI ỌBA ÀWỌN JÚÙ.
39 Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kírísítì, gba ara rẹ àti àwa là.”
40 Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà?
41 Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwá ṣe ni à ń jẹ: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan.”
42 Ó sì wí pé, “Jésù, rántí mi nígbà tí ìwọ́ bá dé ìjọba rẹ.”
43 Jésù sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Lónì-ín ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Párádísè!”