50 Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jóṣẹ́fù, láti ìlú àwọn Júù kan tí ń jẹ́ Arimatíyà. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ènìyàn rere, àti olóòótọ́.
51 Òun kò bá wọn fi ohùn sí ìmọ̀ àti ìṣe wọn; òun pẹ̀lú ń retí ìjọba Ọlọ́run.
52 Ọkùnrin yìí tọ Pílátù lọ, ó sì tọrọ òkú Jésù.
53 Nígbà tí ó sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀, ó sì fi aṣọ àlà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì tí a gbẹ́ nínú Òkúta, níbi tí a kò tẹ́ ẹnikẹ́ni sí rí.
54 Ó sì jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́: ọjọ́ ìsinmi sì kù sí dẹ̀dẹ̀.
55 Àti àwọn obìnrin, tí wọ́n bá a ti Gálílì wá, tí wọ́n sì tẹ̀lé, wọ́n kíyèsí ibojì náà, àti bí a ti tẹ́ òkú rẹ̀ sílẹ̀.
56 Nígbà tí wọ́n sì padà, wọ́n pèsè ohun olóòórn dídùn, òróró ìkunra (àti tùràrí tútù); Wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí òfin.