1 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ọ̀sẹ̀, àwọn obìnrin wá sí ibojì, wọ́n sì mú lọ́fíńdà ti wọ́n tí pèsè sílẹ̀ wá.
2 Òkúta ti yí kúrò ní ẹnu ibojì.
3 Nígbà tí wọ́n sì wọ inú rẹ̀, wọn kò rí òkú Jésù Olúwa.
4 Bí wọ́n ti dààmú kiri níhà ibẹ̀, kíyèsí i, àwọn ọkùnrin méjì aláṣọ dídán dúró tì wọ́n:
5 Nígbà tí ẹ̀rù ń bà wọ́n, tí wọ́n sì dojúbolẹ̀, àwọn ańgẹ́lì náà bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá alààyè láàrin àwọn òkú?
6 Kò sí níhínyìí, ṣùgbọ́n ó jíǹde; ẹ rántí bí ó ti wí fún yín nígbà tí ó wà ní Gálílì.
7 Pé, ‘A ó fi ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn ẹlẹ́sẹ̀ lọ́wọ́, a ó sì kàn án mọ́ àgbélèbú, ní ijọ́ kẹ́ta yóò sì jíǹde.’ ”